Awọn agba bọ wọn ni ailaṣọ lọrun Paaka, o to apero gbogbo ọmọ erinwo. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu igbesẹ kan ti ijọba apapọ ilẹ wa n gbe pẹlu bi wọn ṣe ni pe amulo ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi yoo mu adinku ba ọwọngogo ounjẹ to n ṣẹlẹ lorileede yii lọwọlọwọ.
Ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ni igbakeji aarẹ, Kashim Shetima, ṣalaye pe atunṣe ti ijọba apapọ ṣe sọrọ owo ori ki i ṣe lati fi ara ni wọn, bi ko ṣe igbesẹ kan ti yoo ṣe gbogbo ọmọ orileede yii lanfaani ni.O jọ pe ọrọ yii ni Ẹdun gunle nitori alaye ti oluranlọwọ pataki si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Temitọpẹ Ajayi, ṣalaye pe ṣe ni minisita ọhun ṣelerii pe laipẹ yii ni awọn ọmọ ilẹ Naijiria yoo jẹ anfaani awọn ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi yii.
Ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni ẹni to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede yii , iyẹn Joe Ajaero, ṣabẹwo sileeṣẹ iroyin ‘The Nation’. Asiko abẹwo ọhun ni aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ni pe ọwọngogo owo ọkọ ko ba ma ṣẹlẹ lorileede yii rara ka ni ijọba apapọ ti ko awọn ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi sita lọpọ yanturu. O ni “nigba ti ijọba yii de ti wọn si yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu, ẹgbẹ oṣiṣẹ dabaa amulo ọkọ CNG, iyẹn awọn ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi fun wọn.
Nigeria Latest News, Nigeria Headlines
Similar News:You can also read news stories similar to this one that we have collected from other news sources.
Source: TheNationNews - 🏆 6. / 69 Read more »
Source: DailyPostNGR - 🏆 11. / 59 Read more »
Source: DailyPostNGR - 🏆 11. / 59 Read more »
Fresh Crisis Rocks Rivers Assembly, Pro-Fubara Lawmakers Elect Oko-Jumbo SpeakerThe Latest News from Nigeria and Around the World
Source: channelstv - 🏆 7. / 63 Read more »
Source: DailyPostNGR - 🏆 11. / 59 Read more »
Source: GuardianNigeria - 🏆 1. / 94 Read more »